Atamatase omo agbaboolu ile wa nni to tun figba kan je balogun iko Super Eagles, Mikel Obi ti fise boolu gbigba sile. O loun ko gba boolu mo.
O ni, ko sohun to dun ti kii tan, loun se fise ohun sile.
O ti le logun odun ti omokunrin naa fi gba boolu, o si ni inu oun dun nitori oun sise naa debi ami to si tun lapeere.
O ti figba kan gba boolu fun egbe agbaboolu Chelsea to gba ife eye UEFA Champions League lodun 2012.
Bee ni Mikel gba liigi ile geesi leemeji, idije FA leemeta, idije koopu league ile naa lodun 2007 ati ti Europa lodun 2013. Odun mokanla lo lo pelu Chelsea.
