Ṣeni iroyin agbọsọgbanu iku Babalọja ṣi n jẹ kayeefi, lẹni ti ko ṣaisan rara, koda o to ọgbọn iṣẹju ti wọn lo lọfiisi iyalọja lọjọ yẹn ti wọn fi n ba Alaba onipọnmọ bẹbẹ pe ki wọn dariji i. Alaba alafojudi, ọbun ṣiọṣiọ lọmọbinrin ọhun, omi pọnmọ lo da siwaju isọ ẹ ti wọn baa wi o, lo ba sọ pe ki ẹnikan ma halẹ mo Kayọde oun toripe iyalọja paapaa n gba pọnmọ lọfẹẹ lọwọ oun ati pe ko sibi toun ko le da omi pọnmọ si; toripe oun n ja tikẹẹti isọ meji, nitori naa ki alayọnusọ gbe ẹnu ẹ sọhun un . O ran olofofo niṣẹ o tun ro pe ko ni jẹ ẹ daadaa, niṣoju Morufa ni Alaba ṣe sọrọ naa; ṣebi ẹ ranti Morufa ọmọ aburo iyaloja to maa n ṣeke fun Adisa yẹn, oun lo wa tu pẹrẹpẹrẹ Alaba lọfiisi iya ọja koda o fi kun un pe, ọmọbinrin onipọnmọ naa sọ pe, igba gbogbo niya ọja maa n ranṣẹ wa gba pọnmọ lowo oun. Ṣebi ẹyin naa ti mọ pe ọrọ ẹyin maa n le si i ni, ṣugbọn alasọ jaamu ni Alaba funra ẹ toripe o sọrọ kan to jẹ pe oun ati iyalọja nikan ni wọn mọ si i. Orọ yẹn lo bi iya ọja ninu ti wọn fi sọ pe ki obinrin naa kuro lọja Aṣejere ko maa lọ na ọja rẹ nibomiiran. Ṣe ẹyin naa ri i pe ọfọ nla ni bi wọn ba le eeyan kurọ lọja Aṣejere nitori ẹ ni babalọja ṣe lọ baa bẹbẹ lọdọ iyalọja. Yatọsi pe asọju Alaba pọ, ọmọbinrin naa ṣeeyan, o lawọ, o lọyaya ṣugbọn ẹnu yii naa ni.

Iyalọja ko tiẹ kọkọ fẹẹ gba o, ṣugbọn nigba ti baba ọja ni ki wọn ranti pe owo ti Alaba n pa lọja Aṣejere lo fi n gbọ bukata awọn ọmọ mẹrin ti ọkọ rẹ da silẹ to fi dagbere faye ati pe igba akọkọ ree ti ẹjọ ọmọbinrin naa de iwaju awọn alaṣẹ ọja tori naa ki wọn fi eyi faa leti. Ọrọ iku ọkọ Alaba lo bu omi tutu sọkan iyalọja ti wọn fi dariji i, ṣugbọn wọn sọ pe eyin awọn ko ran pọnmọ mọ, tori ẹ ko ma wulẹ gbe pọnmọ ẹ de iwaju awọn mọ.

Nigba ti sẹkitiri Babalọja sare wọle lọja to kọja, ti iyalọja sọ pe ki emi Adisa nikan lọ sibẹ, ṣebi ẹ ranti pe emi naa dọgbọn sa ti mo sọ pe mo fẹẹ lo pe awọn gende meji wa ki wọn le kun Adisa lọwọ. Mo kuku lọọ pe Tayelolu ati Muraina, emi naa tẹle wọn o ṣugbọn ṣe ni mo ta kete. Ẹ woo, Yoruba laajo o jare! Ani ṣeni Adisa ati Tayelolu bẹrẹ si i fun ara wọn nimọran nipa nnkan ti wọn le ṣe, kii ṣe arun Korona lo ṣe Babalọja wa o. Wọn ni ṣeni ọkunrin naa deede di aya rẹ mu to si n fọwọ gbaa tagbara-tagbara, Babalọja ni aisan ẹjẹ riru tẹlẹ ti dokita si ti sọ fun un pe ko maa sinmi daadaa ṣugbọn oju kii gbaa lo maa n gbe wọn wa sọja lojoojumọ, aisinmi to lo pa Babalọja kii ṣe korona koda Ọlọrun ko ni jẹ ki awa ri ogun korona lọja Aṣejere tiwa. Tayelolu ati Adisa gbiyanju awọn mejeeji ni wọn jọ gbe Babalọja lọ si ọsibitu jẹnẹra toripe ọwọ awọn nọọsi to wa losibitu ọja ko ran an, ṣugbọn wọn ni ko debẹ to fi pajude! Lojuẹsẹ mama sọ pe ki alaago kede ki wọn ti ọja toripe iroyin iku naa ba wa lojiji! Babalọja to fi ẹsẹ ara ẹ rin wọ inu ọja lọjọ yẹn ti di alejo mọṣuari.

Ẹmọ ku; oju opo di, ọpalamba ọti oyinbo fọ, onigbansọ ko ri i sọ. Babalọja Arẹmu Gbadeyanka lọ laarin wa, ko ṣe e pe pada. O di arinnako, o tun doju ala firi, ipade di ọjọ agbedide.

Lọjọ ti wọn ṣe adura ọjọ mẹjọ Babalọja ni Tayelolu ati Adisa di ọrẹ apapandodo, alabosi ni kinni buruku Adisa ọwala yẹn o, ṣe lo n ki Taye ni mẹsan an mẹwaa. Kii ṣe pe wọn ṣe kinni ọhun rẹpẹtẹ, iwọnba ni wọn ṣe e tori ati pa ofin ti ijọba la kalẹ lati pa ajakalẹ arun koronafairọọsi mọ ṣugbọn sibẹ awọn eeyan wa ṣe ẹyẹ ikẹyin fun ẹni rere to lọ. Ka pa ti awada ti, yatọ si pe Babalọja fẹran obinrin, wọn ṣeeyan pupọ, ara ẹ ni nnkan ti wọn ṣe fun Alaba lọjọ yẹn ti wọn o tiẹ mo pe ọlọjọ yoo de, kii ṣe pe Babalọja n fẹ Alaba o. Ta lo tiẹ maa fẹ Alaba ọbun rairai, ọmọbinrin naa sanra, apa ẹ kọọkan dabi itan maalu, ẹsẹ rẹ dabi ti erin lakatabu; o dudu họhọ bẹẹ ni aṣọ ọrun rẹ maa n rin bi isọ olororo, koda aṣọ to n ro fi taja dabi itẹ ọmọ ọbun. Ohun to jọniloju ni bi Alaba ṣe le fi ẹnu rẹ jẹun toripe ko si eyin to mọ ninu kaa ẹnu rẹ, oorun pọnmọ ko jẹ ki eeyan le mọ bi ẹnu rẹ ṣe n run to, lọrọ kan ṣa Babalọja mi ko le fẹ Alaba, afinju ni Arẹmu baba Kadija to doloogbe, o kan ṣe tiẹ fun Ọlọrun ni ati pe o ṣee ṣe ko jẹ pe o ti n wo ibode ọrun lọọkan to fi ṣiṣẹ oloore naa lati fi ra ọrun funra ẹ.

Nnkan kan sọ si mi lọkan, o jọ bi ẹni pe Adisa fẹẹ fa oju Tayelolu mọra, ta ni ko ni i ṣọrẹ ejirẹ, bi eeyan ba fẹẹ ta ọja jere lọjọ Aṣejere ko gbọdọ ko iyan ọmọkunrin naa kere rara koda emi ni mo maa n bẹẹ lọpọ igba to ba fẹẹ lọọ gbe kanta Adisa danu. ṣugbọn ni bayii ti iku Babalọja ti so awọn mejeeji pọ bayii, ta lo fẹẹ maa ba mi da sẹria fun Adisa bẹẹ mo gbọdọ ni paṣan kan lọwọ lati ba alakọri ẹ wi. Mo maa ronu si nnkan ti mo maa ṣe, a ṣi n ṣaaro babalọja lọwọ.

By Asejere

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Follow by Email
WhatsApp