
Aarẹ Muhammadu Buhari ti yọ adari gbogbo awọn ologun ilẹ wa, bẹẹ lo si ti fi awọn ẹlomii rọpo wọn.
Awọn to fi rọpo awọn ologun naa ni Ọgagun Leo Irabor, ti yoo maa dari gbogbo awọn adari ologun, nigba ti Ọgagun I Attahiru, yoo maa ṣakoso awọn jagunjagun ori ilẹ, AZ Gambo, yoo maa ṣakoso awọn jagunjagun ori omi, nigba ti I Alao, yoo ma ṣakoso gbogbo awọn jagunjagun ofurufu.
Ninu atẹjade ti Fẹmi Adeṣina, agbẹnusọ Aarẹ Buhari fi sita sori ẹrọ ayelujara lo ti kede ọrọ naa, bẹẹ lo si dupẹ lọwọ gbogbo awọn ọga ologun to n ba a ṣiṣẹ naa lati ọdun 2015.
