
Oloye Sunday Adeyẹmọ, ti gbogbo eeyan mọ si Sunday Igboho ti sọ ọ di mimo pe loootọ ni Aṣiwaju Bọla Tinubu fun oun ni miliọnu meji naira lọjọ toun pade ẹ nile rẹ to wa ni Bourdilon ni Ikoyi, l’Ekoo.
Igboho Ooṣa sọrọ yii lasiko to n ba gbajumọ oniroyin nni, Dele Momoudu sọrọ lori ẹrọ ayelujara lonii ọjọ Tusde.
O ni, lasiko ti wọn fẹẹ ṣe ibo nipinlẹ Ondo, lasiko ijobaṣ Oluṣẹgun Mimiko, ni Tinubu ke si ọga oun, Alaaji Raṣidi Ladọja, to jẹ baba isalẹ oun. O ni, Ladọja lo fun Tinubu ni nọmba oun lasiko naa, tori awọn ko mọra ri.
Ọkunrin ajijagbara naa tun sọ pe lẹyin naa ni Tinubu pe nọmba oun, o si sọ foun pe koun wa sile oun ni Eko, o ni nigba toun si debẹ, o sọ foun pe koun ma da si ọrọ oṣelu Ondo, tori oun fẹẹ gba ipinlẹ naa mọ PDP lọwọ, o loun si gba si i lẹnu, tori oun ati baba oun Ladọja ti jọ sọrọ nigba naa.
Ṣugbọn Igboho sọ pe nigba toun n lọ, Tinubu fun oun ni miliọnu meji naira, koun fi ra epo si mọto, o ni ko ju bẹẹ lọ, ṣugbọn latigba naa, ko si ajọṣepọ laarin awọn.
