
Ọmọbinrin kan ti n sọrọ sawọn alayọnusọ ti wọn n sọ isọkusọ kiri igboro pe owo ni Ehi Ogbebor, obinrin ti alaga awọn onimọto l’Ekoo, Alaaji Musuliu Akinsanya, ṣẹṣẹ n fọ. Ọmọbinrin yii ni; ko sootọ nibẹ rara, ifẹ lo sun ọrọ oun de ọdọ MC Oluọmọ.
Blessing Osom lorukọ ọmọbinrin naa, o si jẹ ọkan ninu awọn ọrẹ timọ-timọ Ehi, iyawo ọsingin tuntun ti Alaaji Akinsanya ṣẹṣẹ n fẹ.
Bẹẹ o ba gbagbe, laipẹ yii ni Aṣejere sọ fun yin nipa ifẹ ọmọbinrin Ehi yii, ati Alaaji MC Oluọmọ, bi wọn ti fẹran ara wọn, ati bi wọn ti n gbaradi lati ṣegbeyawo laipẹ.
Ṣugbọn, kete ti iroyin naa ti bẹ sigboro lawọn eeyan ti n sọ pe nitori owo lọmọbinrin ara Edo naa ṣe n lẹ mọ MC Oluọmọ kaakiri, ohun to mu ki Blessing da wọn lohun pe, irọ funfun balau, kii ṣe nitori owo o, ifẹ lo sun Ehi de ọdọ MC, ki wọn yee sọ isọkusọ rara.
