Iyabo Ojo

Gbajumọ oṣere tiata Yoruba nni, Iyabọ Ojo ti sọrọ buruku sawọn ololufẹẹ rẹ ti wọn fẹran ati maa tọrọ owo lọwọ ẹ.
Iyabọ fibinu sọrọ yii sawọn alatilẹyin rẹ lori ẹrọ ayelujara, lati fi aidunnu rẹ han si bi awọn alagbe naa ti n fojoojumọ tọrọ owo lọwọ rẹ.
O ni, ko sẹni to lẹtọọ ati maa tọrọ owo lọwọ oun, tori pe wọn jẹ alatilẹyin oun, nitori awọn toun n fun lowo pọ.
“Emi naa n ṣiṣẹ ki n too ri owo mi ni, ẹnu ti mo si n bọ pọ gan an ni, paapaa awọn ọdọ, kẹyin naa lọọ tẹpa mọṣẹ yin, ki ẹ yee tọrọ owo lọwọ mi.” Ohun to sọ niyẹn.

By Asejere

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Follow by Email
WhatsApp