Laipe yii nijoba ipinle Eko ti tun fofin de awon kansu mewaa mi in nipinle Eko, nitori iwa aibikita opo won lawon agbegbe naa. Gomina Babajide Sanwo-Olu pase pe lati ojo kinni, osu kesan-an, odun yii, ko gbodo si ise okada lawon agbegbe kan mo rara. Awon kansu ti won fofin de ise okada niwonyi: Kosofe Local Government, Ikosi-Isherri LCDA, Agboyi-Ketu LCDA, Oshodi-Isolo Local Government, Isolo LCDA, Ejigbo LCDA, Shomolu Local Government, Bariga LCDA, Mushin Local Government ati Odi-Olowo LCDA. Sugbon saaju ikede yii ni komisanna fun eto iroyin ati ogbon inu nipinle Eko, Ogbeni Gbenga Omotoso salaye idi ti ijoba se fee fofin de awon olokada l’Ekoo. Ohun ti won ba SAM AKINROLE so ree.
Gbobgo awon to wa nibi ipade yii ni won fohun sokan pe ki ijoba fofin de ise okada l’Ekoo, ki leyin ri so si eyi?
Mo fee dupe pe e wa fun ipade yii, Gomina Babajide Sanwo-Olu lo fun wa lase lati pe ipade yii pe ki awnon eeyan awi olugbe Eko wa so tenu won nipa oro okada yii. Se e si rii pe awon eeyan ti so tenu won, won fohun so pe ka fofin de ise okada. Kii se nitori awon ewu to wa nibe nikan bii ka kan lese, ka fo lori, sugbon ju gbogbo e lo, nitori eto aabo, won fe kijoba se nnkan nipa ise okada. Nitori awon nnkan wonyi ni won se fohun so pe ka fofin de ise okada yii.
Awon oba alaye kan ni so pe ijoba ko gbodo fofin de ise okada, won tako ka fofin de e, won si so idi ti won fi fe ko ri bee
Enikan so ninu won pe bi eni gba ise lowo awon eeyan wa ni bi a ba le fofin de ise okada l’Ekoo. Sugbon ohun ti awa maa so ni pe kinni kan ni adiye ti n je ki agbado too de, sugbon oba alaye kan naa tun so pe ilu Eko ni awon anfaani to po fun awon olugbe Eko lati kose owo, nitori naa awon eeyan ko gbodo ri ise okada gege bi ise, awon ise gidi ti won le se wa daadaa, ibi ti a si ti le ko won nise naa wa daadaa kaakiri, ki won kan si wa, koda leyin ekose yii, awon irinse wa fun won lati lo. Awon ibi ekose mejidinlogun lo wa, ijoba si tun ma n pese irinse fun won lati bere ise lesekese. Awon akosile tun fihan pe ise okada ko daa rara, awon olugbe Eko si ti soro nibi ipade yii. Opo awon eeyan to soro ni won gba pe ka fofin de okada. Sugbon gomina funra re lo le pase pe ka fofin de e.
Kin ni ohun ti ijoba n se nipa ise awon agbero l’Ekoo, nitori ko daju pe won setan ati fi ise won sile rara, won si n yo awon onimoto lenu?
A ti da igbimo kan sile lati maa bojuto ise won. Looto lawon eeyan n kun lori ise won, sugbon a fe kawon eeyan mo pe awon kan lo n se egbe yii, ti a ko ba fe kawon eeyan segbe mo, kawon eeyan ma darapo mo won. Eni ba maa darapo mo won, tabi sise onimoto gbodo darapo mo won, ijoba ko lase ati fofin de won, bee lawon eeyan n darapo mo won, sugbon bo ba di pe awon eeyan yii ti fe maa koja ofin tabi koja aye won nijoba maa dide lati fofin de won.
Opo awon oko ti ko ni akole tabi nomba ni won n lo kaakiri nipinle Eko bayii, ti won n gbe awon ero lati ibi kan lo si ibi keji. Pelu bi eto aabo ti se n mehe yii, kin ni igbese ti ijoba n gbe lati daabobo awon araalu?
O lodi sofin lati maa lo iru awon oko bee lati fi ko ero lati ibi kan lo sibomi i, ohun ti mo mo ni pe ileese olopaa ko ni fowo kekere mu iru awon oko bee, bi a ba ri enikeni to n fi moto ti ko ni nomba ko ero, won gbodo fowo ofin mu won.
Yoo to eelo tijoba Eko maa padanu bi won ba fofin de awon olokada yii?
Ko siye kan tijoba n ri gba lowo awon olokada, nitori kii se ise ti ijoba fowo si, kii ise ise tijoba gbaruku ti, bi ijoba ba fofin de won, ko si nnkan ti ijoba fee padanu nipa ti owo, nitori ijoba ko ri won gege bii ise ti won gbodo maa san owo kan sapo ijoba.
Awon eto wo le se sile fun awon agbegbe ti ko ni lanfaani mi in yato si okada, bii Ikorodu?
Anfaani mi in tun wa to po, a ti so pe a maa seto fun awon araalu. Fun apeere, ni Ikeja ati pese awon oko onikelebe tawon eeyan le lo, o wa, nitori naa a maa seto fun awon araalu. Sugbon ju gbogbo e lo, yato si awon nnkan wonyi, a tun gbodo wo ohun aburu ti okada mu wa fun agbegbe wa, paapaa nipa ti eto ilera, eto aabo, ati bee bee lo, fun awon odo wa. Gbogbo nnkan wonyi ju ohun ti awon kan n wo lo.

