* Owo ki i ba ni gbe titi, awọn ọdọ gbọdọ kọ bi a ti n de owo mọlẹ
Alaaji Oloye Wasiu Atanda Balogun ni Babaloja Jenera ti gbogbo ipinle Eko yii. Ojo keji, osu kewaa yii gan an ni won pe Aadorin odun. Nibi ayeye naa ni akoroyin wa, OLUWATOYIN MATHNUEL ti ba won ni gbolohun nipa irinajo aadorin odun naa, ohun ti won ba wa so ree.
Babaloja, nitori awon ti ko ti i mo yin, ed daruko daruko yin ni ekunrere
Oruko mi mi Alaaji Oloye Wasiu Atanda Balogun. Babaloja General tipinle Eko, Balogun General ti Ilu Iganmu/Ijora labe Kabiesi Oba Aromire, Basorun ti ilu Awowo labe Oba Abdul-Gafar Tijani.
Aadorin odun lori eepe, e so die nipa irinajo yin?
A bi mi ni agboole Balogun niluu Coker Iganmu nibi, oruko awon obi mi ni Alaaji Lamina Lawal, Rafatu Olorunkemi Balogun. Mo kose owo jorin-jorin (welding) mo si dupe pe mo fi ise yii se ohun rere ti mo le tokasi. Mo lo si ilu Mecca ni igba akoko lodun 1976, mo feyawo akoko mi ti oruko n je Alaaja Morufat Balogun lodun 1973. Laipe mo bere karakata irinse weda ninu oja Abibatu Mogaji ni Coker nibi lati ibe mo wo egbe oloja, kerekere mo je akowe oja, mo je akowe owo oja, nigba to ya Olorun kadara ki n je baba oja fun igba akoko lodun 1979-80. Leyin igba yii, mo ni anfaani ati je Babaloja General ti Surulere labe alaga kansu Mayor Dickson lodun naa lohun-un. Kerekere mo wo tipinle labe iya wa; Abibatu Mogaji ki Olorun bawa fi orun ke won, won gba mi towo-tese, labe irinajo yii mo je akapo egbe Babaloja lapapo, mo tun di alaga oja labe baba oja general, igba naa, Oba Ologudu tiluu Ogudu. Nigba ti Kabiesi fi ipo Babaloja General sile fun ipo Oba pelu atileyin gbogbo Babaloja, Iyaloja ati awon igbimo taa mo si action committee Iya wa; Abibatu Mogaji, won ronu kan mi pe emi ni oye naa kan. Pelu ife mo di Babaloja General ni akoko ti Gomina Raji Fasola naa di gomina Eko. Ayeye naa gara ni gbongan ileejoba ni Alausa lodun naa lohun un. Laipe ni Gomina Fasola fi oye asoju, iyen Ambassador Emeritus pelu iwe-eri damilola. Mo n dupe lowo Olorun pe mo si je Babaloja General ti ipinle Eko di oni yii. Mo rin irinajo lo siluu Meka ati Umra laimoye igba, ope ni fun Olorun Alahu!
Kin ni awon ipenija yin paapaa julo gege bii Babaloja General?
Ipenija wa gege bii Babaloja General, sugbon ogun ti se. Nigba aye iya wa Mogaji a jo n se e ni, iya wa; Folashade Tinubu Ojo ti Olorun yan fun wa naa, a jo wa ni, a de jo n se e, ki Olorun je ki a jo se e pe, ki Olorun si fi orun ke iya wa; Abibatu Mogaji.
Nje e tie ni idojuko tabi ipenija kan to mi yin ri?
Bee ni, ninu irinajo mi kan lodun 2002, oko Baalu agbera pa lati ilu Meka ye ko gunle si Eko, Baalu yii fee ja, sugbon ilu Kano lo papa gunle si. Mi o lero pe mo le wa laye lonii yii tori ojo manigbagbe lojo naa. Ninu gbogbo ero oko Baalu ojo naa, enikan soso lo jade laye, Olorun Oba Allah ko awa ero oko yooku yo. Irinajo ninu aye yii, aye ope lo poju nitori pe Olorun n saanu fun mi, awon Iyawo, omo, omo-omo wa ni alaafia, ope ni f’Olorun Oba.
Awon nnkan wo le feran lati maa se gege bi majesin tabi odo?
Mo feran gbigba eyin ori tabili lopolopo, mo maa n gba a lekookan nigba ti agba de yii naa. Gege bi odo, omuwe ni mi!
Nje e le so isele apanilerin kan ti e se bi ewe tabi odo fun wa?
O maa n pamileri ti mo ba ranti isele kan to sele si mi gege bi odo lodun 1977, mo gun keke alupupu ti mo koko ra lo si inu oja, iyalenu lo je fun mi pe pelu bi mo se fi irin de e mole to gege bi onimo ise irin, ki n too pada de ibi ti mo wa gunle si, awon ole ti ji i gbe, awon ti isele yii soju won ni oko pick-up. iyen oko akeru nigba naa lawon ole naa gbe e si, isele yii pamilerin pupo. Sugbon pelu adura iya mi pe Olorun a bo mi ni asiri, ko to ose merin ti isele yii sele ni Olorun ra oko ayokele akoko fun mi ni apo owo meje aabo, iyen egberun kan ataabo naira, N1,500. Oko yii ni mo n lo titi Olorun fi n se alekun oko ayokele fun mi Alhamdulilai!
Nje e le daruko awon ore ti e jo sewe ti won wa nipo nla bii tiyin bayii lonii?
Bee ni, bo tile je pe iku ti ka ese opolopo lo, sibe mo dupe fun Olorun lori aye fun ilera pipe bayii, ore igba ewe ni Alaaji Yusuf niluu Amuwo, mo dupe fun Alaaji Rasak ‘All for show’ niluu Orile atawon mi in ti won wa laye ati laaye won.
Kinni imoran yin fun awon odo?
Ki awon ewe fi irun dudu sise ki won le ri irun funfun sinmi. Ki awa obi ran omo ni eko iwe nitori oko ale, ki awon odo naa ri i pe awon ka iwe naa de oju ami. Iya eko iwe je mi pupo, sugbon mo dupe fun Olorun ni eni yii pe ninu awon omo ti Olorun fun mi mo ni graduate mesan an, onimo omowe PHD, Masters wa ninu won. Ki awon obi jare to omo ni eko iwe. Ki awon odo maa de owo mole, ki won fi owo ti won ba ri fi se ohun to dara nitori owo ki i ba eniyan gbe titi.
Kinni imoran yii fun awon Oloja?
Mo gba gbogbo oloja nimoran ki won mu imototo oja ni okunkundun, ki won maa toju oja ni gbogbo igba kii se ojo Ojobo nikan ni ojo imototo oja, ki won ma ju ile si oju kota, tabi ibi ti ojo le ti i sinu kota, ki won maa san owo LAWMA dede.
Fun awon omo Naijiria nko, paapaa lasiko ibo odun 2023?
Yoruba bo won ni; ‘Enu eni la fi n ko meeje’ asiko ti de fun gbogbo wa lati yan ire, lati dibo wa fun eni to to pelu PVC. Ka dibo fun Asiwaju Bola Ahmed Tinubu, pelu iranlowo Olorun Asiwaju nikan lo le tun orile-ede Nigeria se. Lati ori alaga council ni, ijoba ipinle, asoju nileegbimo, e je ka dibo wa fun eni to ye, ta loye naa to si, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ni.
Odun Aadorin ti e pe lori ile aye yii, bawo le se ri i si?
Mo dupe fun Olorun pe mo wa laye, mo wa laaye, mo ri ohun wo, mo ri ohun tokasi Alhamdulilai, ope ni fun Olorun.

