Alaaja Tawakalitu Balogun, ni Iyaloja Jenera ti Oriade, won si tun je iyawo Babaloja Jeneral tipinle Eko, iyen Alaaji Wasiu Balogun. Won ti ba Asejere soro nipa oko won, ati iriri won nile oko. Ohun ti won ba OLUWATOYIN MATHNUEL so ree

 

E ku ayeye ojoobi Aadorin odun ti Babaloja General, e ba wa daruko yin?

Iyaloja Oriade: E se e pupo, oruko temi ni Alaaja Tawakalitu Balogun, emi ni Iyaloja Genera ti Oriade, mo si je Iyawo Babaloja General tipinle Eko.

E ti fe oko yin to odun meloo bayii?

Ka bu u kere ati le ni ogbon odun ti mo ti fe oko mi

Iru eniyan wo loko yin je?

Alaaji Wasiu Balogun, eeyan ni walahi! Oko daadaa ni, oko to n toju iyawo ati awon omo ni, ti ko fi mi sile nigba kookan, gege bi iyawo to wa lati inu idile nla, oko mi ko je ki eera ko ra mi. Jije Iyaloja ati Iyaloja general lonii yii kii se mi mo on se mi bikose atileyin oko mi. Mo n dupe fun Olorun fun aarin emi ati baale mi. Won duro ti mi gan an, ki Olorun ba mi duro tiwon pelu ilera pipe. Walahi leyin Olorun Oba Allah, oko mi lokan.

Iyaloja ma iru ounje wo loko yin feran julo?

Baale mi ko feran eba, sugbon won feran obe efo, ogede dudu sise ati iresi. Babaloja general kii jeun pupo, bo tile je pe won kii tete jeun. Bee ni Alaaji Wasiu Balogun kii rera, won ni itelorun bee ni won feran ounje asaraloore, ki Olorun tubo ba mi lora emi won ki won dagba ki won dogbo ninu ilera pipe ati alaafia ti i se oogun oro.

Iyaloja, kin ni asiri ewa yin?

E se e mo dupe! Alaaji Wasiu Atanda Balogun Babaloja general ipinle Eko ni asiri ewa mi nitori won fi mi lokan bale. Won ko ba mi ninu je, ti nnkan ba n gbe mi lokan soke boya lori isele ninu oja, ti mo ba fi lo won bayii, won a gbe e fuye ninu okan mi. Se e mo pe ti eeyan paapaa julo obinrin ba n ridunnu, ewa re a maa jade lotun-lotun ni. Ki Olorun tubo maa dun awon naa ninu.

E sadura fun oko yin fun ti ayeye Aadorin odun

Adura mi fun won lojo oni yii ni pe, a o tun jo pejo se ayeye ogorin, adorun, ogorun odun ni lagbara Olorun  ninu ilera to pe ati alaafia. Ki  Olorun ma fi omo dawa laamu, ki a ma ri isoro lori omo, ki Olorun je ki a ni idunnu latara omo lola Olorun Oba Allahu.

 

By Asejere

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Follow by Email
WhatsApp