Ọtunba Gbenga Daniel, gomina ipinlẹ Ogun tẹlẹ, to tun jẹ alakoso eto ipolongo ibo fun Alaaji Atiku Abubakar, to dije fun ipo Aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP lọdun 2019, ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC.
Aarọ oni Tusde niroyin naa jẹyọ.
Ohun taa gbọ ni pe, Gbenga Daniel maa gba kaadi ẹgbẹ APC lonii, ki eto iforukọsilẹ ti wọn n ṣe lọwọ too pari. Bẹẹ niroyin fi ye wa pe eto ti n lọ lọwọ fun oun atawọn alatilẹyin rẹ lati darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC.
Bẹẹ o ba gbagbe, kete lẹyin ti wọn pari eto idibo ọdun 2019 ni Gbenga Daniel, tawọn ololufẹ ẹ maa n pe ni OGD kede rẹ pe oun ko nifẹẹ ati ṣe oṣelu mọ, ati pe oun fẹẹ gbajumọ iṣẹ toun yan laayo.
Ṣugbọn, latigba naa la gbọ pe awọn oloṣelu mejeeji; APC ati PDP ti fa a pe ko waa darapọ mọ ẹgbẹ awọn, ko too di pe iroyin tuntun yii jẹyọ.
A gbọ pe laipẹ ni OGD maa ṣepade pẹlu awọn agba inu ẹgbẹ oṣelu APC, paapaa awọn Gomina Abubakar Atiku Bagudu tipinlẹ Kebbi, Nasir El-Rufai tipinlẹ Kaduna ati Badaru Abubakar tipinlẹ Jigawa.


