Gomina ana nipinlẹ Ọṣun, Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla ti kilọ fẹgbẹ oṣelu APC, iyẹn ẹgbẹ to n ṣe nipinlẹ naa pe ki wọn kiyesara fun awọn ọta ti wọn foju jọrẹ ti wọn darapọ mọ ẹgbẹ naa ati ti wọn fẹẹ darapọ mọ ẹgbẹ.

Arẹgbẹṣọla to tun jẹ minisita fun eto abẹle nilẹ wa kilọ yii lasiko too le ṣe iforukọsilẹ oun atawọn mọlẹbi rẹ ninu ẹgbẹ naa ni wọọdu rẹ niluu Ileṣa, nipinlẹ Ọṣun. Ni wọọdu rẹ to wa ni Ifofin, ni wọọdu kẹjọ, nijọba ibilẹ Ileṣa East lo ti ṣe iforukọsilẹ naa.

Nigba to n ba ogunlọgọ ero ti wọn waa pade rẹ nibi eto naa sọrọ, Arẹgbẹ ni, o di dandan ki ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ naa kiyesara fun awọn ti wọn fẹẹ maa gba wọle, awọn ti wọn n ṣe bii ọrẹ, ṣugbọn to jẹ ọta ni wọn, awọn to jẹ pe igi da ẹyẹ fo ni wọn, o ni ki ẹgbẹ naa ṣọra fun wọn, bi wọn ti n gba iru wa ogiri wa wọle, nitori igi da ẹyẹ fo ni wọn.

Bo tiẹ jẹ pe Arẹgbẹ ko darukọ ẹnikan, ṣugbọn awọn eeyan to mọ bi ọrọ oṣelu ṣe n lọ nipinlẹ naa sọ pe latigba ti aarin oun ati Gomina Gboyega Oyetọla ko fi bẹẹ dan mọran mọ, ni gomina ti fa oju Sẹnetọ Iyiọla Omiṣore mọra.

Bẹẹ o ba gbagbe, laipẹ yii ni Omiṣore darapọ mọ ẹgbẹ naa, koda Oyetọla funra rẹ wa ninu awọn to waa pade rẹ lọjọ to darapọ mọ ẹgbẹ naa. N lawọn eeyan ṣe n sọ pe Omiṣore ni Arẹgbẹ n ju oko ọrọ naa lu.

O ni, loootọ lanfaani wa fun awọn apaayan, awọn ole, jẹgudujẹra ati bẹẹ bẹẹ lọ lati darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC, ṣugbọn, ẹtọ ẹgbẹ naa ni lati kiyesi awọn to n darapọ mọ ẹgbẹ.

By Asejere

Follow by Email
WhatsApp