Gomina AbdulRahman AbdulRazaq, Alaaji Bolarinwa, ati Alaaji Lai Mohammed nibi ipade

Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti fidi rẹ mulẹ pe, Ọnarebu Bashir Ọmọlaja Bọlarinwa tawọn eeyan mọ si BOB, ṣi ni alaga ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) nipinlẹ Kwara.
O ti kọkọ sọrọ yii ninu atẹjade kan ti akọwe iroyin gomina, Rafiu Ajakaye fi ranṣẹ si Aṣejere laarọ ọjọ Jimọ Fraide oni.
Bakan naa ni gomina tun fidi ọrọ naa mulẹ nibi ipade awọn alẹnulọrọ ẹgbẹ naa to waye n’Ilọrin, lọjọ Fraide naa.
Lara awọn to wa nibi ipadẹ ọhun ni minisita fun eto iroyin nilẹ wa, Alaaji Lai Mohammed, ati alaga ẹgbẹ naa funra rẹ, Alaaji Bọlarinwa atawọn agbaagba ẹgbẹ mi in.
Ipade yii waye lati fidi iṣakoso rẹ mulẹ, ati lati sọ fawọn alabosi pe BOB ṣi ni alaga ẹgbẹ ni Kwara, ati pe ko sohun to le mu ede aiyede wa sinu ẹgbẹ ọhun rara, gẹgẹ bawọn alabosi kan ti n gbe e kiri.
Alẹ Alamisi Tọsde ana yii niroyin dede ṣẹyọ pe awọn ọmọ igbimọ ẹgbẹ APC ni Kwara ti yọ Alaaji Bolarinwa nipo alaga naa, bẹẹ ni wọn si tun n sọ ọ kiri pe Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti fọwọ si iyọnipo alaga naa, ṣugbọn gomina ti sọ bayii pe ko sẹni to le da ẹgbẹ naa ru, BOB ṣi ni alaga.

By Asejere

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Follow by Email
WhatsApp